terça-feira, 19 de fevereiro de 2008

ORIKI ÈṢÙ

ÈṢÙ ỌTA ÒRÌṢÀ
ỌṢẸTURA LORUKỌ BABA MỌỌ
ALAGOGO IJA LORUKOIYA NPEE
ÈṢÙ ODARA ỌMỌ KUNRIN IDOLOFIN
OLE ṢONṢON SORI ẸSẸ ẸLẸSẸ
KOJẸ KOSI JẸKI ẸNI NJẸ GBE MI
AKI I LOWO LAI MUTI ÈṢÙ KU RO
AKI I LAIỌ LAI MUTI ÈṢÙ KU RO
AṢỌ TUN ṢOSI LAI NI ITIJU
ÈṢÙ APATA SỌMỌ ỌLỌMỌ LẸ NU
AFI OKUTA DI PO YIỌ
ALAGẸMỌ ORUN A NLA KA LU
PA PA WARA A TU KA MA ṢE ṢA
ÈṢÙ MA ṢE MI OMO ELOMIRA
NI KO ṢE

Nenhum comentário: